Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ló wà nílùú Abuja, Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Bwari, Ìjọba ìbílẹ̀ Gwagwalada, Ìjọba ìbílẹ̀ Amac, Ìjọba ìbílẹ̀ Kwali, Ìjọba ìbílẹ̀ Kuje, àti Ìjọba ìbílẹ̀ Abaji.
Ní àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ yìí, ètọ̀ ìdìbò ààrẹ sí n lọ ní ìrọwọ́ àti ìrọsẹ̀.

Andrew Barry tó jẹ́ asojú European Union tó darí àjọ EU láti ṣe àbójútó ibi ètò ìdìbò ààrẹ ṣe ń lọ tún sọ pé àwọn wá láti wá bójútó ibi ètò ìdìbò ààrẹ ṣe ń lọ nílùú Abuja, gẹ́gẹ́ bí olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi ránṣẹ́ sí wọn pé àwọn yóò rí i pé ètò ìdìbò lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀

Ó tún sọ pé lẹ́yìn ti ètò ìdìbò náà bá parí, àwọn yóò fi ìròyìn wọn ránṣé sí àjọ EU tó rán wọn wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Lára àwọn to tún wá sàmójútó ètò ìdìbò ààrẹ nílùú Abuja ni àjọ tó ń gbógun ti ṣíṣe owó-ìlú kúmọ-kùmọ lórílẹ́-èdè Nàìjíríà láti rí i pé àwọn ènìyàn kò ta ìbò tàbí ra ìbò wọn. Àjọ ECOWAS náà wà níbẹ̀.
Leave a Reply