Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Kí Dókítà Pate Kú Oríìré Fún Yíyàán Sí Ipò Gẹ́gẹ́ Bí Olùdarí Àgbà Gavi

0 253

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí kí Olùdarí Àgbà àtí Aláṣẹ tí Gavi Vaccine Alliance, Dókítà Muhammad Ali Pate. Ó sọ pé òún ní ìrètí látí ṣiṣẹ́ ní pẹkipẹki pẹ̀lú rẹ̀ látí mú ètò ìlera orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lágbára sí àtí àwọn ọrọ̀ ìlera àgbáyé mìíràn.

Ààrẹ Buhari ṣàpèjúwe Dr Pate gẹ́gẹ́ bí òún ìwúrí fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ilẹ̀ Áfíríkà lápápọ̀. Nítorí pé òún ní Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí yóò ṣé Olùdarí Àgbà àtí Aláṣẹ ilé iṣẹ́ Gavi.

Tún kà nípa; Abẹ́rẹ́ Àjẹsára ààrun ìgbẹ́ gbuuru tán mọ́ Malawí lọ́wọ́

Ààrẹ náà sọ pé, “Ìrètí wá ní pé Dókítà Pate yóò ló ìmọ, ìmọràn àti ìrírí rẹ̀ nínú ìṣàkóso ilé iṣẹ́ náà tí yóò sì jẹ́ òun èlò fún ilẹ̀ Áfíríkà àtí gbogbo àgbáyé látí dẹkùn ikú àwọn ọmọdé.

“O kú oríire, inú wà dùn fún àwọn àṣeyọrí rẹ̀,” ní Ààrẹ náà sọ.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button