Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò Ọdún 2023 – Makinde Ṣèlérí Láti Sọ Odò Adágún Ado-awaye Dì Ibùdó Ìgbafẹ́

1 186

Ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbo ti ọdún 2023, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí láti sọ Odò adágún tó wà ní ìlú Ado-Awaye di ibùdó Igbafẹ fún Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí o ba jáwé olubori léèkejì nínú ìdìbò to n bọ.

Makinde lo sọ ọrọ yìí ni Ààfin Alado ti ìlú Ado-Awaye, Ọba Ademola Folakanmi lásìkò tó n ṣe ìpolongo ìbo níbi tí o ti jẹ kí o di mímọ fún Ọba Folakanmi wí pé ìjọba Ìpínlè Ọ̀yọ́ yóò kọ Ibùdó Igbafẹ ti ìgbàlódé di ilu Ado-Awaye.

Gẹgẹ bíi atejade ti akọwe ìròyìn fún Gómìnà, Taiwo Adisa fi síta, Makinde jẹ ki o di mímọ pé ìṣèjọba òun yóò bèrè sí san ìdá mẹwàá nínú ìdá ọgọrun ìpín owó ìjọba ibilẹ fún àwọn ìgbìmò olóyè láti ọjọ Kerinlelogun oṣù Kejì ọdún yìí lọ ní ìbámu pẹlú ìlérí rẹ.

Gómìnà wa fi kun ọrọ rẹ̀ nígbà tí o sọ pé gbogbo ìlérí ati ohun tí òun tí ṣe nínú sáà akọkọ ìṣèjọba ní òun yóò mọ lé ní sáà ẹlẹẹkeji.

Bákan náà ní Gómìnà tún bá àwọn adari Ẹgbẹ́ Ọmọ Lẹyin Kristi ní ilé ìjọsìn ‘First Baptisti Church’ to wà ni agbegbe Oluwole ni ìlú Iseyin sọrọ ti o sì rọ gbogbo wọn láti gba rùkù tí àwọn tó n dije du ipò kan tàbí òmíràn labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ki gbogbo wọn bà lè jáwé olubori nínú ìdìbò gbogboògbò to n bọ.

O wa tún ṣèlérí fún àwọn agbarijọ Imaamu ati Aafa ní ilé Imaamu Olajori tó kalẹ sí Òkè Suna ní ìlú Ìséyìn, wí pé òun yóò máa ṣe déédéé pẹlu gbogbo ẹlẹsin ni ìpínlè Ọ̀yọ́.

Nígbà tí o n feesi, Alado ilu Ado-awaye, Ọba Folakanmi lù gómìnà Makinde lógò ẹnu, tí o sì ṣàpèjúwe rẹ gẹgẹ bíi ẹni tí o tayọ nínú ìtàn àwọn gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. O wá fi àsìkò náà gba gómìnà níyànjú láti se àwárí àwọn ibùdó Igbafẹ míràn ni Ìpínlè Ọ̀yọ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

One response to “Ìdìbò Ọdún 2023 – Makinde Ṣèlérí Láti Sọ Odò Adágún Ado-awaye Dì Ibùdó Ìgbafẹ́”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button