Take a fresh look at your lifestyle.

Abẹ́rẹ́ Àjẹsára ààrun ìgbẹ́ gbuuru tán mọ́ Malawí lọ́wọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 244

jàkálẹ̀-ààrùn ìgbẹ́ gbuuru tí ó burú jùlọ lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn ti ba orílẹ̀-èdè Malawí, ní èyí tí ó fa gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára ṣùgbọ́n tí a gbọ́ pé ó ti fẹ́rẹ̀ tán.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn agbègbè, agbẹnusọ fún Ilé-iṣẹ́ tó ń rísí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba, Adrian chikumbe,sọ pé orílẹ̀-èdè kò ní abẹ́rẹ́ àjẹsára náà mọ́.

Malawí gba abẹ́rẹ́ tó lé ní Mílíọ́nù méjì láti ọ̀dọ̀ Gavi-supported Global Oral Cholera Vaccine Stockpile ní oṣú kọkànlá.

Àwọn agbègbè ilé-ìwòsàn mọ́kàndín-lọ́gbọ̀n lórílẹ̀-èdè ni ààrùn ìgbẹ́ gbuuru kọlù láti ìgbà tó ti kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ nínú oṣù kẹta,ọdún 2022.

Àwọn ẹgbàáẹ̀rinlá- ó -lé- ní- ẹ̀jọ -dín – lọ́gọ́je ni ààrùn náà ti dá lágara, tí ènìyàn ẹẹ̀rìn- dín -ní- okòó-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rún sì ti jẹ́pè ọlọ́run.

Leave A Reply

Your email address will not be published.