Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀ Èdè France Se Ìrànlọ́wọ́ Owó Fún Ìdàgbàsókè Ètò Ọ̀gbìn Ní Nàìjíríà

0 247

Ìjọba orílẹ̀ èdè France ti mú ìgbòòrò bá ètò ọ̀gbìn ní orílẹ̀ èdè Nàìjìríà pẹ̀lú pípèsè owó tí ó lé mílíọ̀nù kan owó ilẹ̀ òkèèrè (1.2m Euro). Èyí tí ìrètí wà pé yóò mú àlékún bá ìpèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.

 

Mínísítà Ètò Ìsúná àti ti ètò Ọ̀gbìn ni ó se asojú fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà tí wọ́n ń se ayẹyẹ ìfọwọ́síwèé láàrin orílẹ̀ èdè méjéèjì.

 

Ìrètí wà pé ilé iṣẹ́ kan láti orílẹ̀ èdè France ni yóò se àkósò ètò náà pẹ̀lú ìkúnlọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button