Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ Adójútòfò Pèsè Ohun Èlò Ìlera Fún Àwọn Ilé Ìwòsàn Ní Ìpínlẹ̀ Kano

0 316

 

Kò dín ní Ilé ìwòsàn mẹ́ẹ̀rin ní ìpínlẹ̀ Kano tí ó ti jẹ ànfààní ìpèsè àwọn ohun èlò ìlera láti ọwọ́ àjọ tí ó ń mójútó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, lójúnà àti se ìgúnpá fún àwọn tí ó lùgbàdì omíyalé àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ míràn.

 

Nígbà tí ó ń se àfihàn àwọn ohun èlò náà, alákòsóo àjọ náà, Mustapha Habib-Ahmed sọ wípé àwọn ohun ẹ̀bùn náà wá láti ọwọ́ Ilé-Iṣẹ́ (Map International) fún àwọn Ilé ìwòsàn ní Ìlúu Kano.

 

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano dúpẹ́ lọ́wọ́ àjọ adójútòfò fún àtìlẹyìn wọn, Ó sì rọ àwọn tí ó jẹ ànfààní àwọn ohun èlò náà láti lò wọ́n bí ó ti ṣe yẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button