Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ UN Pé Ìpè Fún Ìdásílẹ̀ Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Jígbé Ní Orílẹ̀-èdè Burkina Faso

0 261

 

Àjọ UN, àgbáríjọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, àti orílẹ̀-èdè Faranse ti pè fún ìdásílẹ̀ ní kíámọ́sá láì gba ohunkóhun kankan àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Obìnrin tí wọ́n Jígbé ní orílẹ̀-èdè Burkina Faso ní ọjọ́ Kejìlá àti ọjọ́ kẹtàlá oṣù yìí.

Kọmísọ́nà àgbà ti Àjọ UN fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, Volker Türk sọ wípé ó ya òun lẹ́nu láti máa gbọ́ pé wọ́n jí àwọn ènìyàn gbé pàápàá jù ìdojúkọ ìjínigbé ti àwọn Obìnrin ní ilẹ̀ Burkina Faso.

Àjọ US State Departments sọ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ká òun lára, ó sì ti ojú ṣú òun.
Nínú àtẹ̀jade kan, ilẹ̀ Faransé bú ẹnu àtẹ́ lu ọ̀ràn náà, wọ́n ṣì pè fún Ìdásílẹ̀ wọn lọ́gán.

Kò sí ẹnikan tabi àgbáríjọpọ̀ kankan tó sọ wípé àwon wà nídìí isẹ́ ibi náà, sùgbón ìjínigbé náà wáyé níbi tí àwọn ológun agbésùnmọ̀mi gbilẹ̀ sí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button