Ògbóǹtarìgì Oǹkọrin Afrobeat ọmọ Nàìjíríà, orin Wizkid ‘Made In Lagos’ ti gba àmì ẹ̀yẹ keji lori àtẹ Billboard ti ọdún 2022 tí ti Burna Boy’s ‘Love, Damini’ náà sì wà nínú àmì ẹ̀yẹ mẹwa àkọkọ.
‘Made In Lagos’ tí wọ́n gbé jáde nínú ọdún 2020 jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kerin tí Wizkid’s gbé jáde. Àwo ‘Made In Lagos’ tẹ̀lé BTS’s ‘Proof’ tó gba àmì ẹ̀yẹ ìkinni lórí àtẹ Billboard ọdún 2022 tí wọ́n tẹ̀ jáde.
‘Made In Lagos’ yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tó ń lo ọgọ́rùn ún ọ̀sẹ̀ lórí àtẹ orin àgbáyé tó sì tún gùn jù lọ tó kọjá ti oǹkọrin Fela ‘The Black President’ tíí se àrùn lé lógójì ọ̀ṣẹ̀ orin rẹ́kọ̀dù.
Bákannáà láàrin àmì ẹ̀yẹ mẹwàá àkọ́kọ́ lati rí Love, Damini’ ti ọdún 2022 tí Oǹkọrin Burna Boy ti òun náà se ipò kẹsàn án (9th) bótilẹ̀jẹ́pé ó gbée jáde ní oṣù keje.
CKay’s 2019 EP ‘CKay pẹ̀lú àwo orin àkókọ́ rẹ̀ tó gbé jáde ‘Love Nwantiti’ parí pẹ̀lú ipò kẹrìnlá lórí àtẹ òpin ọdún.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply