Abẹ́rẹ́ Ebola yóò dé sí Uganda laipẹ.
Olórí àjọ WHO Africa ti pàjàwìrì sọ wípé ìgbésẹ nlọ lọ́wọ́.
Láti ìgbà tí àrùn náà ti bù jáde ní ogúnjọ́ oṣù kẹsán, kòkòrò náà ti tàn káàkiri orílè-èdè náà tí ó sì ti fa ọwọ́ ètò ẹ̀kọ́ sẹ́yìn, ó ṣì ti dé olú ìlú náà, Kampala.
Ènìyàn márùn dín lọ́gọ́ta ti kú gégébí àjọ
Centers for Disease Control and Prevention se sọ.
Láti ìgbà ti àrùn náà ti sú yọ bí òsùmàrè, àwọn agbéra pá tó ń ta Ìjọba lólobó ni wọ́n ti gbé kalẹ̀ tí wọ́n ṣì ń ṣiṣẹ́ wọn lóòrèkóòrè.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kewàá, Olórí àjọ World Health Organization(WHO) ti kéde ìfilọ́lẹ̀ ìdánwò abẹ́rẹ́ Èbólà láti dojúkọ Sudan strain ti Èbólà tó súyọ ní orílè-èdè Uganda.
Mínísítà ètò ìlera sọpé, orílè èdè Uganda ń borí ipènijà náà.
Èbólà ń tàn ká nípasẹ̀ omi ara, ìfarahàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ibà, èbíbì, ẹ̀jẹ̀ jíjàade lára àti ìgbẹ́ orìn.
Bí àjọ WHO se sọ, ìtànkálẹ̀ àrùn náà parí nígbàtí kò sí ọ̀tun ìsúyọ àrùn náà mọ́ ní ọjọ́ meéjìlélọ́gbọ̀n léraléra, ẹ̀ẹ̀méjì ti àrùn náà n gbaradi.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply