Ní ọ̀nà láti fi òpin ṣí àdánù lẹ́yìn ìkórè oko àti ọ̀nà láti jẹ́ kí owó lórí irè oko pọ̀ síi láàrin àwọn àgbẹ̀ ọ̀gbìn Tòmátì, Àádọta àgbẹ ti gba ìdánilékọ̀ọ́ láti ọwọ́ àjọ National Horticultural Research Institute (NIHORT).
Ní àkókò ìdánilékọ̀ọ́ náà ti aṣòfin tó ńsojú Akure South/North Federal Constituency , ọ̀gbẹ́ni Alade Lawanson,
se kòkárí rẹ̀, Olùdarí NIHORT, Dr. Mohammed Àtàndá sọ pé ìgbésẹ náà yóò ro ètò ọrọ̀ ajé lágbára àti ìdàgbàsókè ohun gbogbo tí wọ́n fi Tòmátì se. Alákóso ètò nípa ìwádìí, Dr. Olagorite Adetula, Atanda náà sọ bákannáà.
Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé, ẹ̀kọ́ náà yóò fún ìjọba lágbára láti ní ọ̀nà ètò ọrọ̀ ajé míràn, yóò jẹ́ kí wọn tún dojúkọ ètò ọ̀gbìn gégébí ọ̀nà kan gbógì, ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé tí àwọn akǒpa bá mú ẹ̀kọ́ náà lò, ìpàdánù irè oko kòní sí mọ́.
Bí o tilè jé pé orílẹ̀-èdè ede yìí jé ẹ̀kerìnlá nínú ìpèsè Tòmátì láàgbáyé, èkejì ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, Nàìjíríà ṣì tún jẹ́ asàgbéwọlé ketàlá Tòmátì láàgbáyé ati ìkẹta ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ látàrí ìpamọ́ rẹ̀.
Onímọ̀ Sáyẹ́nsì kan ní NIHORT,
Dr. Joel Akinfasoye fi kún pé ìwúlò Tomati pò jojo fún àpẹẹrẹ, wọ́n leè lọ̀ọ́ lúbúlúbú sí Ketchup,tẹ pọ̀rọ̀(paste), tàbí ìlò ní gbígbẹ (dried), Juisi (juice) àti wáínì(wine).
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply