Ọbabìnrin ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Elizabeth Kejì tó lo iye ọdún tó gùn jù nínú ìtàn àwọn ọba ni ilé gẹ̀ẹ́sì ti kú ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún. Ayaba gun orí àpèèrè ní ọdún 1952, o si jọba fún aadorin ọdún.

Ayaba kú ikú àlàáfíà ni ọsan ọjọ́bọ̀ ni Balmoral Castle, àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ ìdílé ọba lọ kéde ikú re.

Ọba Charles tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ ti wà ní Balmoral yóò sì padà sí ìlú London ni ọjọ́ jímọ̀. Àwọn ọmọ ìdìlé ọba mìíràn náà tún ti rin irin-àjò lọ sí Balmoral, pẹ̀lú ọmọ-ọmọ rẹ̀ Ọmọọba William, ẹni tí o jẹ àrólé báyìí.

Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply