Orílẹ̀ Èdè Jámínì tún ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ẹ̀ṣọ́ Ìṣàyẹ̀wò rẹ ní ìlà oòrùn Mali.
Èyí jẹ́ ara iṣẹ kí àlàfíà kó jọba rẹ̀ ti Àjọ Àgbáyé tí a mọ̀ sí United Nations Multidimensional Integrated Stabilization Mission in Mali, MINUSMA.
Èyí wá lẹ́hìn tí àwọn ológun ti dáwódúró àwọn iṣẹ́ ṣíṣe rẹ̀ ní oṣù tó kọjá nígbàtí ìjọba orílẹ̀ èdè Málì ti kọ àwọn ẹ̀tọ ìfòkáàkiri lóri afẹ́fẹ́ àwọn ọmọ ogun.
Arábìnrin agbẹnusọ ologun náà sọ pé “àwọn iṣẹ́ ìsọdọ̀tun àkànse isẹ́ àwon ológun ní ìta ìlú Gao tún ti bẹ̀rẹ̀.”
Ó sọ pé ẹ̀gbẹ́ kan tí ó de Gao láìpẹ́, “ti ṣetan ni kikun lati ṣiṣẹ, ati pe o ti gba iṣẹ ṣiṣe ti aabo ibudó naa.”
Ìròyìn rò pé púpọ̀ jùlọ àwọn ológun Jámínì ni Málì wà nítòsí Gao.
Níbàyí, ní ọjọ́ kejìlá Oṣù Kẹjọ , ilé-iṣẹh ààbò sọ pé òun ti dá ìṣèwádìí tàbí alamí àti àwọn iṣẹ́ tí ó jọmọ dúró lẹ́hìn ìgbàtí ìjọba Málì ti kọ ìgbaniláàyè fún awọn ọkọ̀ òfúrufú láti ṣe àtìlẹyìn àwon ọmọ ológun lábẹ́ iṣẹ́ MINUSMA ti UN.
Wọ́n se ìfilọ́lẹ̀ MINUSMA ni ọdun 2013 lati ṣe iranlọwọ fun Mali lati koju ipolongo Jihadi to n ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
Ọ̀ràn náà ti pẹ́, ó sì tí gba ẹ̀mí àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwon ènìyàn tí ó sì ti fi ipá mú ọ̀kẹ́ aimoye ènìyàn sá àsálà kúrò nílé wọn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply