Ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀,HOS, Dókítà Fọláṣadé Yẹmí-Ẹ̀san, ti fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí ìwà àìṣedéédé àwọn ilé-iṣẹ́ dójútòfò lórí àìsanwó àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó ti jẹ́pè ọlọ́run.
Inú Dokita Yẹmi-Ẹsan kò dùn fún bi àwọn ilé iṣẹ́ bánigbófò ṣe ń ṣe ségesège lori ojuṣe wọn,o fi eyi han nibi ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ dójútòfò ‘Group Life Insurance Policy For Civil Servants’, ní ìlú Àbújá, ó sọ pé “àwọn tí ó ti kú kò le jà fún ara wọn.”
O ṣọ pe, pẹlu gbogbo igbiyanju Ijọba Apapọ lati ri pe ẹbi oṣiṣẹ ijọba to jẹpe ọlọrun gbe igbe aye irọrun nipa sisan ẹtọ wọn ni kiakia , awọn ile-iṣẹ dojutofo ati Awọn alagbata n ṣe idiwọ awọn akitiyan naa nipasẹ awọn iwa aiṣedeede wọn.
HOS sọ pe aiṣe iṣẹ wọn bo ṣe tọ,bo ṣe yẹ ko ni jẹ itẹwẹgba ati pe wọn gbọdọ ṣe atunṣe lori rẹ.
Leave a Reply