Ìjọba Zamfara ní ọjọ́ Àìkú, ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ Ìtọ́jú Ìlera abélé, PHC tuntun mẹ́tàlé-lógójì, tí ó sì tún ń pín àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé àwọn aláárẹ̀ mẹ́tàdín-láàdọ́jọ láti ṣe àlékún wíwà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn iṣẹ́ ìlera ní ìpinlẹ̀ náà.
Awọn ile-iṣẹ ilera yii ni wọn kọ labẹ eto ijọba lati pese ile-iṣẹ eto ilera abẹle ni ọkọọkan ninu awọn agbegbe ẹgbẹ oselu mẹtadin-laadọjọ ipinlẹ naa.
Gómìnà Bello Matawalle sọ nínú ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ ìlera tí wọ́n ti parí ní Sabongida, ní ìjọba ìbílẹ̀ Bungudu, pé àwọn PHC tó ṣẹ́ kù wà ní oríṣiríṣi ìpele lati parí.
Gẹgẹ bi Ẹni to ṣoju fun un,iyẹn Igbakeji rẹ, Sen. Hassan Nasiha, gomina sọ pe awọn PHC mẹtale-logoji wa ni igbaradi kikun lati pese awọn iṣẹ ilera to dangajia fun awọn alaisan ni ipilẹ.
Leave a Reply