Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Ghana ti ní ọ̀ràn kòkòrò apànìyàn Marburg fún ìgbà àkọ́kọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 387

Orílè-èdè Ghana ti ní àwọn ènìyàn méjì tó ti ní kòkòrò apànìyàn Marburg,àjàkálẹ̀ ààrùn tí ó farajọ kòkòrò tó ń faa Ebola.

Ajọ Agbaye to n mojuto eto  Ilera (WHO) ,ṣe afihan eyi ninu ọrọ kan ni Ojobo,o sọ pe awọn alaisan mejeeji naa ku laipẹ ni ile-iwosan kan ni agbegbe gusu Ashanti.

Awọn alaisan meji ni agbegbe gusu Ashanti yii ni awọn ami aisan igbẹ gbuuru, iba,inu rírun ati eebi, ṣaaju ki wọn to ku ni ile-iwosan,gẹgẹ bi alaye naa ṣe sọ.

Awọn oṣiṣẹ ilera ni orilẹ-ede Iwọ-oorun Afirika sọ pe, eniyan mejidin-lọgọrun ti wọn fura si gẹgẹ bi olubaṣepọ pelu wọn ni o ti wa labẹ ipinya bayi.

Ko ti si itọju sibẹsibẹ  fun Marburg – ṣugbọn awọn dokita sọ pe mimu omi pupọ ati atọju awọn ami aisan kan pato le ṣeranlọwọ fun alaisan naa lati yeebọ.

Kokoro naa  tan sara eniyan lati ọdọ awọn eso adan ti o si le tan kaakiri laarin eniyan nipasẹ  omi ara.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.