Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìwòsàn gbogbonìṣe Sókótó Gba ẹẹ́tàdín-láàdọ́ta-lé-lọ́ọ̀dúnrún mílíọ́nú Náírà Fún Àtúnṣe, Ohun èlò ìgbàlódé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 409

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Sókótó ti fọwọ́sí iye owó tótó mílíọ́nù mẹ́tàdín-láàdọ́ta-lé-lọ́ọ̀dúnrún Náírà fún àtúnṣe gbogbogbòò àti ìpèsè àwọn ohun èlò ìgbàlódé ní Ilé-ìwòsàn gbogbonìṣe ní ìpínlẹ̀ náà.

Dokita Nuhu Maishanu, Oludari Ile-iwosan (CMD) naa, sọ eyi di mimọ lakoko ti o n ba awọn oniroyin sọrọ ni Sokoto.

Gẹgẹ bi o ti sọ, ifọwọsi yi da lori idojukọ iṣẹ lati mu ki atunṣe naa pari lasiko ati ipese ohun elo.

O fi kun pe, lẹyin ti atunṣe ba pari, ile-iwosan naa yoo ti kunju osunwọn lati pe ni  ile-iwosan gbogbonìṣe kan.

Maishanu dupẹ lọwọ Gomina Aminu Tambuwal fun itẹwọgba naa, o tọka si pe, eyi  ṣe afihan ipinnu ijọba ipinlẹ naa lati mu idagbasoke ba eto ilera ni ipinlẹ naa.

Leave A Reply

Your email address will not be published.