Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé tí ń ta Epo sí ilẹ̀ òkèèrè (OPEC), Mohammad Sanusi Barkindo, ti jẹ́ ìpè olúwa.
Ọgbẹni Barkindo di oloogbe ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, gẹgẹ bi ọfiisi akọwe OPEC ati Oludari Alakoso Ile-iṣẹ to n ṣeto Epo ilẹ Naijiria, Mele Kyari ṣe fi sita.
Lọjọ Iṣẹgun, Aarẹ Muhammadu Buhari gbóríyìn fún Barkindo ni ile ijọba to wa ni Abuja fun awọn aṣeyori nla to ṣe ni OPEC.
Akoko rẹ gẹgẹ bi Akọwe-Agba OPEC yoo pari ni Oṣu Keje yii.
Aarẹ ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi aṣoju ti o yẹ fun orilẹ-ede.
Leave a Reply