Ilé-ẹ̀kọ́ gíga fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣirò ICAN, ṣe ìlérí láti túnbọ̀ gbéṣẹ́ rẹ̀ lárugẹ
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé-èkọ́ gíga fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣirò ní ìlú Awka, gúúsù ilà-oòrùn Nàìjíríà, ti ṣe ìlérí láti tọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ́nà láti jẹ́ alámọ̀dájú irú ẹ̀ lágbáàyé, tí ó sì sọ pé ilé-ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àgbáyé àkọ́kọ́.
Ọgbẹni Kingsley Chukwuemeka Dim ṣe ileri naa lasiko ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gẹgẹ bi Alaga keje ile-ẹkọ giga naa,agbegbe Awka.
Ọgbẹni Dim sọ pe erongba oun gẹgẹ bi igbimọ tuntun ni lati je ki gbogbo aye mọ ICAN,bu iyi kun awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn fun wọn ni ipo to jọju ni ibi iṣẹ wọn, ati rii daju pe akiyesi pataki wa fun ipo ẹgbẹ naa.
Iwuye naa tun waye pẹlu ifilọlẹ Igbimọ Alaṣẹ agbegbe ti ọdun 2022 si 2023 nipasẹ Aarẹ ẹlẹẹkeji-din-lọgọta ile-ekọ giga naa lorilẹ-ede, Mallam Tijjani Musa Isa, ti Iyaafin Ngozika Okoye , ti o jẹ Komisona fun Isuna tẹlẹ ni Ipinlẹ Anambra ṣoju ẹ.
Leave a Reply