Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpàtẹ ọjà Kwara : Gómìnà Abdulrazaq Ṣèlérí Àtìlẹyìn Fún Àwọn oníṣòwò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 290

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ní ìparí ọ̀sẹ̀ ti ṣe ìlérí àtìlẹ́yìn nígbà gbogbo fún àwọn ọ̀dọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ipa nínú àwọn ilé-iṣẹ́ orísirísi.

Gomina naa sọrọ ni Ilorin, olu-ilu ipinlẹ naa, nibi aṣekagba ipatẹ ọja Awọn ọdọ  Ipinlẹ Kwara keji,ipatẹ ti  ijọba ṣeto lati ṣe agbega iṣowo laarin awọn ọdọ ati mu agbegbe dara julọ pupọ fun awọn iṣowo lati gberu.

AbdulRazaq, ẹni ti o ṣabẹwo si gbogbo awọn ibudo ipatẹ mẹ̀ta- lé -ní -okòó lé-lọ́ọ̀dúnrún ti awọn ọdọ oniṣowo ṣẹsẹ kọ,o sọ pe ituyaya nla naa jẹ iwuri  fun ijọba lati tunbọ maa ṣatileyin fun wọn.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button