Ìjọba Nàìjíríà ti gba ẹgbàajì lé ní- irínwó àwọn òògùn àjẹsára ààrùn còrónà ti Johnson & Johnson tí ìjọba àti àwọn ènìyàn Sípènì fi tọrẹ fún Nàìjíríà.
Nigba ti o n sọrọ nibi ayẹyẹ ranpẹ, lati samisi ifijiṣẹ ajẹsara naa nipasẹ ijọba Ilu Sipeeni, Oludari Alase ti ile-iṣẹ to n mojuto eto itọju ilera lorilẹ-ede (NPHCDA), Dokita Faisal Shuaib sọ pe awọn eniyan to fẹrẹ to ọgbọn miliọnu ti o yẹ ti gba ajẹsara iwọn lilo akọkọ ti gba.

O sọ pe ida naa duro fun ida mẹtale-logun ati die awọn ti o yẹ ki o gbaa.
Dokita Shuaib tun sọ pe,akitiyan ijọba apapo n pọ si lati rii daju pe aadọrin ninu ọgọrun awọn ọmọ orilẹ-ede ti o yẹ ki gba ajẹsara naa loti gba.
Leave a Reply