Take a fresh look at your lifestyle.

A kò ní lọ sílú òkèèrè fún ìtọ́jú ara mọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 365

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé orílẹ̀-èdè  ti ṣetán láti di ibùdó-àjò fún àwọn tó ń lọ sí òkèèrè fún ìtọ́jú ara.

Minisita fun Alaye ati Aṣa, Alhaji Lai Mohammed ṣe afihan eyi ni ọjọ iṣẹgun nigba ti o bẹrẹ irin-ajo lọ si ile-iwosan Duchess International Hospital ti o wa ni Ikẹja,ni ilu-Eko,guusu iwọ oorun, Naijiria.

Nipa ṣiṣe bẹẹ, aṣa irin-ajo fun itọju ara yoo dinku ni Naijiria.

Lọwọlọwọ bayii, awọn aririn ajo fun itọju ara lati ọpọlọpọ apakan Iha Iwọ-oorun Sahara ti Adulawọ ti n wa gba itọju ara nibẹ.

Minisita naa sọ pe awọn iṣẹ ti ile-iwosan naa yoo maaṣe yoo din ẹẹdẹgbẹta  biliọnu naira ti awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria  n na lori irin-ajo itọju ara ku ni ọdọọdun,igbesẹ ti yoo tọju ifiṣura ajeji ati alekun owo ilẹ okeere.

Oye  ile-iwosan Duchess International ni lati mu itọju ilera agbaye todangajia ni iwọn owo ti ko jara lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button