Hajj Ọdun 2022: FCTA Ṣètò afikún owó àsansílẹ̀ fún Àwọn Arìnrìn àjò mímọ́ Hajj
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àjọ àwọn mùsùlùmí ti ìṣàkóso ìjọba àpapọ̀ olú ìlú Nàìjíríà, FCTA, ti fún àwon arìnrìn àjò mímọ́ láti se Hajj odun yìí ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia títí di ọjọ́ kẹtàlá oṣù karùn-ún láti fi kún owó àsansílẹ̀ tí wọ́n san, kí ìgbìmọ̀ Hajj orílẹ̀-èdè tó kéde owó Hajj gangan.
Oludari Igbimọ, Mallam Muhammad Nasiru Danmallam, sọ eyi lasiko ti o n ba awọn to fẹ rinrin ajo sọrọ lakoko ipele keji ẹkọ ati iṣalaye ti o waye ni ipari ose ni Hajj Transit Camp ti o wa ni ilu Abuja.
Danmallam ṣalaye pe sisan kun owo irinajo Awọn aririn ajo yoo jẹ ki Igbimọ ṣeto ikọrukọ silẹ fun awọn arinrin ajo lọ si Saudi Arabia.
Leave a Reply