Take a fresh look at your lifestyle.

Jíjẹ mimú lọ́pọ̀ janturu fún ìṣínu ààwẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 477

Àwọn Mùsùlùmí ní orílẹ̀-èdè Ígípítì ti péjọ lẹ́bàá tábílìì tí ó gùn san an nan lópòópónà láti ṣínu ààwẹ̀ wọn lápapọ̀ pẹ̀lú oúnjẹ “Iftar”lóríṣiríṣi lọ́pọ̀lọpọ̀, ní agbègbè Matariya, ní ariwá ilà-oòrùn ti olú-ìlú Ígípítì ní Cáírò.

Iṣẹlẹ iyanu naa ko ẹgbẹẹgbẹrun awọn Musulumi ati awọn Kristiani papọ nitori pe ajọjẹ naa  waye  lakoko aawẹ Ramadan.

Awọn oluṣeto gbagbọ pe apejọ naa yoo mu iṣọkan wa laarin awọn eniyan lati oriṣiriṣi  orilẹ-ede ati ẹsin .

Awọn eniyan bii ẹgbẹrun mẹfa laarin agbegbe ni o kopa ninu apejọ alarinrin yii ti o kun fun awọn ọṣọ.

Awọn aladugbo agbegbe naa tun wa lati gbadun ounjẹ ati oju-ọjọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button