Àwọn Mùsùlùmí ní orílẹ̀-èdè Ígípítì ti péjọ lẹ́bàá tábílìì tí ó gùn san an nan lópòópónà láti ṣínu ààwẹ̀ wọn lápapọ̀ pẹ̀lú oúnjẹ “Iftar”lóríṣiríṣi lọ́pọ̀lọpọ̀, ní agbègbè Matariya, ní ariwá ilà-oòrùn ti olú-ìlú Ígípítì ní Cáírò.
Iṣẹlẹ iyanu naa ko ẹgbẹẹgbẹrun awọn Musulumi ati awọn Kristiani papọ nitori pe ajọjẹ naa waye lakoko aawẹ Ramadan.
Awọn oluṣeto gbagbọ pe apejọ naa yoo mu iṣọkan wa laarin awọn eniyan lati oriṣiriṣi orilẹ-ede ati ẹsin .
Awọn eniyan bii ẹgbẹrun mẹfa laarin agbegbe ni o kopa ninu apejọ alarinrin yii ti o kun fun awọn ọṣọ.
Awọn aladugbo agbegbe naa tun wa lati gbadun ounjẹ ati oju-ọjọ.
Leave a Reply