Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò ń darí àpèjọ lórí ayélujára

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 324

Ìpàdé ọlọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀  Ìgbìmọ̀ Aláse àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Ọjọ́bọ̀ pẹ̀lú Igbákejì ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò.

Ọjọgbọn Ọṣinbajo  lo n ṣe alaga ipade naa nitori   Aarẹ Muhammadu Buhari to wa ni ilu Paris, Faranse, fun abẹwo ọlọjọ kan gẹgẹ bi alejo Aarẹ Emmanuel Macron pelu fun Apero Alafia Paris ọlọjọ mẹta.

Awọn minisita ti o wa nijoko nibi ipade naa , eyiti o bẹrẹ ni agogo mẹwa owurọ, ni ti Ilera, Osagie Ehanire; Isuna, Inawo ati Eto Orilẹ-ede, Zainab Ahmed; ati Ofurufu, Hadi Sirika.

Adajọ agba lapapọ ati Minisita fun Idajọ, Abubakar Malami; ati Minisita fun Isuna ati  Eto Orilẹ-ede, Clem Agba,naa tun wa nijoko  nibi ipade naa.

Lara awọn oṣiṣẹ ijọba agba miiran  to tun wa nibi ipade naa ni ọga agba fun awọn oṣiṣẹ  aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari; ati Akowe Yẹ,ile-iṣẹ to n mojuto inawo ẹda abẹmi , Dokita Habiba Muda Lawal, ti o ṣe aṣoju Akowe fun Ijọba apapọ.

Awọn alaye nigbamii.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button