Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbò Anambra: Charles Sólúdò jáwé olúborí

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

53

Àjọ olómìnira elétò ìdìbò   orílẹ̀-èdè INEC, ti kéde Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Sólúdò ti All Progressive Grand Alliance (APGA) gẹ́gẹ́ bí olúborí lápapọ̀ nínú ìdìbò gómìnà Anambra ọdún 2021.

Ni ipari, ni nnkan bii agogo kan aabọ owurọ ọjọru , ọga agba fun ipadabọ , Ọjọgbọn Florence Obi, ti o tun jẹ igbakeji ọga Yunifasiti ti Calabar, kede ẹni to gbegba olubori labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance (APGA) Ọjọgbọn Chukwuma Soludo gẹgẹ bi olubori ninu ibo to ṣẹṣẹ pari nibi idibo Gomina Anambra 2021 .

Ọjọgbọn Chukwuma Soludo, eni to ru asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance (APGA) ni ipo akọkọ pẹlu ibo ẹgbàá-le-ni-ọ̀kẹ́-màrún-abo o le ni oókànlá din ni ojì-le-nigba ,ti  Ọgbẹni Valentine Ozigbo, ẹni to n ru asia ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) wa ni ipo keji pẹlu ibo ẹgbàájì-le-ni-ọ̀kẹ́-mèjì-abo din ni ẹ̀ta le ni àádọ́wá, nigba ti Andy Uba ti o wa labẹ asia  All Progressive Congress (APC) tẹle lẹhin pẹlu ibo ẹgbẹ́ẹ́ẹdógún-le-ni-ọ̀kẹ́-mèjì o le ni ẹ́ẹdógún din ni ẹ̀wá dinlọ́ọ̀dúnrún laarin awọn ẹgbẹ mejidin-logun  miran ti wọn kopa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.