Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí yóò ṣèfilọ́lẹ̀ ìpàdé àpérò fún ìdáábòbò ètò ẹ̀kọ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 253

Ààrẹ orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpàdé àpérò káríayé ìpele kẹrin, fún ìdáábòbò ètò ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀.

Eleyi jẹyọ ninu  alaye kan ti  Oludari iroyin ile-iṣẹ eto ẹkọ, Ben Bem Goong fọwọ si.

Apero naa eyiti o jẹ ajọgbekalẹ orilẹ-ede Naijiria, Sipeni, Nọwe ati Ajẹntina ni ero lati ṣe atunwo ilọsiwaju  awọn orilẹ-ede ti o jẹ ọmọ ẹgbẹ  lati  ṣe eto aabo topeye fun awọn ile-iwe kariaye.

Ọrilẹ -ede ọgọrun kan ati mejila, pẹlu Naijiria ni o fọwọ si ilana eto ifilọlẹ idaabobo Awọn ile –iwe naa.

Naijiria ni o kọkọ ṣagbatẹru iru eto naa ni orilẹ-ede adulawọ.

Awọn olukopa yoo wa nibi apero ọhun, eyiti aarẹ yoo kede ṣiṣi rẹ ni olu Ile-iṣẹ eto ọrọ-ajẹ fun awọn orilẹ-ede adulawọ (ECOWAS) ni ilu Abuja,ti awọn miran yoo si kopa ninu rẹ lori ayelujara kaakiri agbaye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button