Ààrẹ Bùhárí yóò ṣèfilọ́lẹ̀ ìpàdé àpérò fún ìdáábòbò ètò ẹ̀kọ́
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpàdé àpérò káríayé ìpele kẹrin, fún ìdáábòbò ètò ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀.
Eleyi jẹyọ ninu alaye kan ti Oludari iroyin ile-iṣẹ eto ẹkọ, Ben Bem Goong fọwọ si.
Apero naa eyiti o jẹ ajọgbekalẹ orilẹ-ede Naijiria, Sipeni, Nọwe ati Ajẹntina ni ero lati ṣe atunwo ilọsiwaju awọn orilẹ-ede ti o jẹ ọmọ ẹgbẹ lati ṣe eto aabo topeye fun awọn ile-iwe kariaye.
Ọrilẹ -ede ọgọrun kan ati mejila, pẹlu Naijiria ni o fọwọ si ilana eto ifilọlẹ idaabobo Awọn ile –iwe naa.
Naijiria ni o kọkọ ṣagbatẹru iru eto naa ni orilẹ-ede adulawọ.
Awọn olukopa yoo wa nibi apero ọhun, eyiti aarẹ yoo kede ṣiṣi rẹ ni olu Ile-iṣẹ eto ọrọ-ajẹ fun awọn orilẹ-ede adulawọ (ECOWAS) ni ilu Abuja,ti awọn miran yoo si kopa ninu rẹ lori ayelujara kaakiri agbaye.
Leave a Reply