Ọ̀gá àgbà fún àwọn ọmọ ogun bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò Ìdánilẹ́kọ́ ìdárayá orí pápá
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìdárayá orí pápá fún àwọn ọmọ ogun mẹ́ta Nàìjíríà ní ọjọ́ àìkú,ọjọ́ kẹrin, Oṣù Kẹwàá ọdún 2021, ní Emene ní ìpínlẹ̀ Enúgu, gúúsù ìlà-oòrùn Nàìjíríà, ọ̀gá àgbà fún àwọn ọmọ Ológun (COAS) ,ajagun Faruk Yahaya ti bẹ̀rẹ̀ sí níṣiṣẹ́ lórí ìhùwàsí àwọn ìsọ̀rí àti àwọn àgbékalẹ̀ ní Èbònyì àti Àwọn ìpínlẹ̀ Anambra ní ṣísẹ̀ n tẹ̀lé.
Iṣẹ akọkọ ti ajagun Yahaya kọkọ nawọ mu ni 24 support t Engineer Regiment ni Abakaliki, nibiti o ti tẹtisi si eto iṣẹ ṣiṣe latẹnu Alaṣẹ, ti o si rọ awọn ọmọ ogun lati jẹ alamọdaju ninu ihuwasi wọn lakoko ati lẹhin idanilẹkọ naa,ti o si n mu dawọn loju pe ohun yoo ṣe atilẹyin fun wọn lati ṣe iṣẹ wọn doju ami.
Ni Abakaliki, COAS ṣe abẹwo si Gomina Ipinle Ebonyi, onimọ-ẹrọ Dave Nwaeze Umahi ti o si gboriyìn fun fun gbogbo igbiyanju rẹ lori gbigbogun ti iwa ipanle ni Guusu ila oorun.

COAS dupẹ lọwọ gomina ati awọn gomina gusu ila -oorun miiran fun awọn akitiyan wọn lati ri daju pe alafia ati aabo tun pada si gbogbo guusu ila –oorun gẹgẹ bi Oludari, Ibatan Gbogbogbo Ọmọ ogun, Brigadier General Onyema Nwachukwu ṣe ṣalaye.
Leave a Reply