igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijiria, ọjọgbon Yemi Osinbajo ni yoo maa fi ilu Abuja silẹ lọ si London lati lọ soju aarẹ Muhammadu Buhari nibi ipade ijiroro ajọ agbaye lori iyipada ohun amusagbara lorile ede Afirika, paapaa julọ ni orilẹ ede Naijiria.
Agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ , Laolu Akande lo tun sọ pe ọjọgbọn Osinbajo yoo maa jiroro pẹlu oludari COP26, Alok Sharma,ti o jẹ adari ijọba fun orilẹ ede UK ati alaga fun ijọba ajọagbaye COP26 .
Leave a Reply