Igbákejì ààrẹ,Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀sínbàjò polongo ìtẹ̀sìwájú lórí Ìṣòwò iṣẹ́ àkànṣe Gáásì ní ìlú adúláwọ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò sọ pé àwọn akitiyan ti ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ láti fi òpin sí ìdàgbàsókè àwọn iṣẹ́ àkànṣe gáásì ní ilẹ̀ adúláwọ̀ lòdì sí àwọn ìpilẹ̀ aìṣegbé àti ìṣedéédé tí ó wà nínú àwọn àdéhùn àgbáyé.
O sọ eleyii di mimọ lakoko ti o n sọrọ nibi apejọ lori ayelujara, ti akọle rẹ jẹ: Oju -ọjọ, Rogbodiyan, ati eto bi awọn eniyan ṣe pọ si ni adulawọ, ti ẹgbẹ to n mojuto rogbodiyan lagbaye, ẹgbẹ ọba adulawọ,ati awọn atẹjade Asiri Adulawọ lapapọ n ṣagbekalẹ rẹ loni.
Ọjọgbọn Ọsinbajo maa n sọrọ ni awọn apejọ lọlọkan ọjọkan lori nina owo lori akanṣe iṣẹ gaasi ni awọn orilẹ-ede to sese ndagbasoke, bii Naijiria, ti o si n ṣagbero fun iyipada to ṣedeede ati ilowosi ti otunbọ munadoko si ibi-afẹde ti Net-Zero Emission ni ọdun 2050.
Nibi ipade kan ti o waye ni oṣu keji pẹlu ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti Ilu Gẹẹsi ati Alakoso COP26, Ọgbẹni Alok Sharma, Ọjọgbọn Osinbajo tun tẹnumọ iṣatilẹyin ati ifaramọ Naijiria lori adehun Iyipada oju-ọjọ, ti o si tọka si awọn idiwọ lori ninawo si awọn iṣẹ akanṣe gaasi ni awọn orilẹ-ede adulawọ bi ifaseyin ti o lagbara.
Leave a Reply