Aarẹ Muhammadu Buhari yoo lọ si ipinlẹ Adamawa lonii yii ti o jẹ ọjọ Ẹti.
Aarẹ Buhari lọ lati sedaro pẹlu gomina ipinlẹ naa nipa ikú oloogbe Ahmed Joda, to jẹ ọkan pataki ninu ọmọ ipinlẹ naa to pakòdà.
Joda ni alaga igbimọ to n mojuto gbigbe ijọba kalẹ̀ fun aarẹ Buhari lọdun 2015.
Akọni naa ku ni ọ̀sẹ̀ to koja lọjọ Ẹti ni ọjọ kẹtala, osu kẹjọ , ọdun yii.Ọmọ ọdun ọ̀kan -le-ni-àádọ́rùn (91) ni Ahmed Joda ki o to dagbere faye pé, o digbose.
Aarẹ Buhari yoo tun lo anfaani ọhun lati fi ilu Yola silẹ lọ si ipinlẹ Kano,lati wa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọkunrin rẹ iyẹn , Yusuf Buhari.
Aarẹ Buhari yoo pada lọ si ilu Abuja lẹyin igbeyawo naa.
Leave a Reply