Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari ń lọ sí ìpínlẹ̀ Adamawa

101

Aarẹ  Muhammadu Buhari yoo lọ si ipinlẹ Adamawa  lonii yii ti o jẹ ọjọ Ẹti.

Aarẹ Buhari  lọ lati sedaro pẹlu gomina ipinlẹ naa nipa ikú oloogbe Ahmed Joda, to jẹ  ọkan  pataki ninu ọmọ ipinlẹ naa to pakòdà.

Joda ni alaga igbimọ  to n mojuto gbigbe ijọba kalẹ̀ fun aarẹ Buhari lọdun  2015.

Akọni naa ku ni ọ̀sẹ̀ to koja lọjọ Ẹti  ni ọjọ kẹtala, osu kẹjọ , ọdun yii.Ọmọ ọdun ọ̀kan -le-ni-àádọ́rùn (91) ni Ahmed Joda ki o to dagbere faye pé, o digbose.

Aarẹ Buhari yoo tun lo anfaani ọhun lati fi ilu Yola silẹ  lọ si ipinlẹ  Kano,lati wa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọkunrin rẹ iyẹn , Yusuf Buhari.

Aarẹ Buhari yoo pada lọ si ilu  Abuja  lẹyin igbeyawo naa.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.