Ààrẹ Muhammadu Buhari kò ni pẹ́ di adari ẹgbẹ́ (PAGGW) ni oṣu kẹsan an, ọdun 2021.
PAN-GGW, jẹ ẹgbẹ́ tiwọn gbé kalẹ̀ lati mu iyipada rere bá àwọn ilẹ Afirika ati lati mu ipinnu wọn sẹ latí yí ìgbésí ayé miliọnu awọn eniyan padà.
Minisita fun eto ayika lorilẹ -ede Naijiria, Mohammad Abubarka lo salaye yii fun awọn oniroyin niluu Abuja lori awọn idagbasoke ti ajọ rẹ ti se ní ẹ̀ka ayika, paapaa julọ lorilẹ ede Naijiria. O tẹsiwaju pe ipa pataki ti orilẹ-ede Naijiria ń kó lati koju iyipada ojú-ọjọ́ ati gbigbogun ti awọn ibajẹ nipa ti ayika , yii ni o fun aarẹ ni anfaani lati jẹ adari ẹgbẹ́ Pan-Afirika (PAGGW).
Leave a Reply