Mẹrindinlọgọta awọn ikọ̀ ọlọtẹ ati ẹbí wọn lo ti jawọ ninu isẹ́ ibi wọn bayii , ti wọn si ti fi ikọ ọlọtẹ wọn silẹ.
Eleyii waye nipa bi wọn awọn ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria se n gbógun ti ikọ ọlọtẹ ni igbó Sambisa ti wọn farapamọ sí.
Ikọ ọmọ ogun Hadin Kai. ti n se gudu gudu meje, yaya mẹfa lati sekọlu si ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ , ni eyi ti o fi jẹ ki wọn fira wọn silẹ , ti wọn si jawọ ninu isẹ́ ibi wọn.
Agbẹnusọ fun ile- isẹ ologun orilẹ ede Naijiria,ọgagun Onyeam Nwachukwu, naa tun fidi rẹ mulẹ pe , ikọ ọlọtẹ ni wọn wa funra wọn, ti wọn si tun ko ibọn ati awọn ohun ija oloro ti wọn fi n se isẹ ibi wọn silẹ , lati jawọ ninu isẹ ibi wọn, ki wọn si fi ẹgbẹ buruku ọhun silẹ.
O ti le ni ọgọrun un ikọ̀ ọlọtẹ ti wọn ti fi ara wọn silẹ fun ikọ ọmọ ogun orilẹ ede Naijiria lati kuro ninu ẹgbẹ ibi wọn,laarin ọ̀sẹ̀ meji bayii.
Adari ile-isẹ ologun orilẹ ede Naijria,ọgagun Faruk Yahaya ti gbosuba fun ikọ ọmọ ogun orilẹ ede yii fun iwa akinkanju wọn , o wa tun rọ̀ wọn lati maa kaarẹ nipa gbigbogun ti ikọ ọlọtẹ titi ti wọn yoo fi pòórá bi isó ni orilẹ ede Naijiria.
Leave a Reply