Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ pa gbogbo àwọn ọ̀daràn pátápátá run lórílẹ̀ ède Naijiria-Aarẹ Buhari

42

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà , Muhammadu Buhari  ti korò ojú sí bí àwọn ọ̀daràn se ń pa àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, bí eku pàápàá jùlọ ní àwọn  ìpínlẹ̀ Zamfara àti Kaduna

Aarẹ Buhari wa tun rọ awọn ile-isẹ ọmọ ogun ati ajọ eleto aabo lorilẹ ede Naijiria, ki wọn tun fún sòkòtò wọn le  lati yanju isoro eto aabo to n dojukọ awọn ipinlẹ kan lorilẹ ede yii.

Aarẹ  Buhari wa tun koro oju si awọn oloselu kan  ti wọn n sọ ọrọ kùnbá-kùngbé   lori eto aabo , o wa rọ wọn lati darapọ mọ ijoba lọna ati wa ojutuu si isoro to n dojukọ eto aabo lorilẹ ede yii.

Aarẹ wa fi aidunnu rẹ han lori  awọn  eniyan to ti padanu ẹ̀mí wọn , o wa rọ ajọ eleto aabo lati dena awọn ikọlu to  n sẹlẹ lorilẹ ede yii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.