Take a fresh look at your lifestyle.

Aarẹ Buhari ti se gudugudu méje, yàyà mẹ́fa fún Nàíjíríà- Gomina Jigawa

0 89

Gomina ìpínlẹ̀ Jigawa , Muhammadu Badaru ti gbóríyìn fún ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà , Muhammadu Buhari fún gudu gudu méje , yàyà mẹ́fà tí ó ń se fún gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà,pàápàá jùlọ lórí pípèsè àwọn ohun amáyédẹrùn àti àtúnse tó gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́ , gbàwobọ̀ lórí ètò ọrọ̀ ajé.

Gomina sọrọ yii nibi ayẹyẹ  ti wọn se lati fi ki asofin  Bent (PDP – Ila Gusu Adamawa ),kaabọ sinu ẹgbẹ oselu  All Progressives Congress (APC) lọjọ Abamẹta ni ilu  Yola.

Asofin Bent  fi ẹgbẹ oselu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oselu  APC, o tun jẹ ọkan lara igbimọ alakoso fun ẹgbẹ oselu PDP (BOT) ki o to darapọ mọ ẹgbẹ oselu  APC. Bakan naa ni Bent tun ti se asoju fun ẹkun  ila Gusu ni ipinlẹ  Adamawa  nile igbimọ asoju sofin laarin ọdun  2007 si 2011.

Badaru ni ijọba  aarẹ  Buhari ti se aseyege ti alakan n sepo paapaa julọ lori idagbasoke ti o ti mu ba awọn nnkan amayedẹrun bii  oju irin, ina mọna-mọna , papa ọkọ oju ofurufu  ati idagbasoke to ti mu ba tẹru-tọmọ lorilẹ ede Naijiria.Idi niyi ti awọn kan se n fi .egbẹ oselu wọn silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oselu APC

Gomina ipinlẹ Yobe ti o tun jẹ adele  alaga fun  igbimọ to n samojuto ilana ẹgbẹ oselu  APC naa tun ki asofin  Bent kaabọ sinu ẹgbẹ oselu APC.

Buni, ti o soju fun adari ile igbimọ asofin tẹlẹri , Ken Nnamani  wa sọ fun Bent pe ẹgbẹ osleu APC ko ni fi silẹ ninu awọn ipinnu ti wọn yoo maa se  nipa ẹgbẹ wọn.

Ọjọgbọn  Tahir Mamman, ti o jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oselu APC naa wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oselu APC lati wa ni ọkan , ki wọn si fọwọsowọpọ, ki ẹgbẹ oselu APC tun lee jawe olubori ninu eto idibo to tun n bọ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.