Igbákejì ààrẹ yóò darí ìpàdé ìgbìmọ̀ àpapọ̀ lóríi ayélujára
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìpàdé ìgbìmọ̀ àpapọ̀ ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ ní víllà, tí igbákejì ààrẹ,Yẹmí Òshínbàjò ṣe adarí rẹ̀ ,nígbàtí ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ńkópa níbi àpèjọ ìsúná àwọn adúláwọ̀ kan ní Paris, ní orílẹ̀ -–èdè Faransé.
Ipade naa waye ni yara apejọ obinrin akọkọ,ni deede agogo mẹwa owurọ.
Akọwe ijọba apapọ,Mustapha ati ọga agba fun awọn oṣiṣẹ aarẹ,ọjọgbọn Ibrahim Gambari wa ni ijoko nibi ipade ọhun.
Ṣaaju ibẹrẹ ipade naa, wọn ṣe ipalọlọ iṣẹju kan ni ibọwọ fun Minisita fun Awọn Obirin tẹlẹ, Hajia Aisha Al-Hassan ti o jẹpe ọlọrun ni ọsẹ to kọja, ti o si jẹ ẹni ọdun mọkanle-lọgọta.
Leave a Reply