Àwọn ènìyàn ńlá,olówó ló ń se agbódegbà fáwọn ọlọ̀tẹ̀ ní Nàíjiríà-Abubakar Malam
Ademọla Adepọju
Mínísítà fún ètò ìdájọ́ lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà,Abubakar Malami, ní ìwádìí ti fihàn pé àwọn ènìyàn ńlá àti olówó kan ló ń fowó sèrànwọ́ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ lórílẹ̀ èdè Naijiria, àwọn ko si ni pẹ́, pè wọ́n lẹjọ́.
Malami sọrọ yii lọjọ Ẹti, niluu Abuja lasiko to n ba awọn akọroyin ile aarẹ sọrọ , lẹyin adura ti wọn ṣe ni mọsalasi ile aarẹ.
o ni : “Ni awọn ọdun kan sẹyin, awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria kan lọwọ lati maa se agbodegba fun awọn ọlọtẹ nipa sise iranwọ owo fun wọn lati orilẹ ede United Arabs Emirate , ni eyi ti yoo ran orilẹ ede Naijiria lọwọ ninu iwadii yiii.
“Iwadii si n lọwọ , o digba ti iwadii ba pari , ki a to mọ iye awọn ti wọn lọwọ nibi isẹ ibi ọhun,, sugbọn mo fi n daa yin loju pe iye wọn ko mọ niwọnba.”
O tun fi da gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria loju pe ko si ninu gbogbo awọn onisẹ ibi wọnyi, ti ijọba yoo daa silẹ”
Leave a Reply