Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ènìyàn ńlá,olówó ló ń se agbódegbà fáwọn ọlọ̀tẹ̀ ní Nàíjiríà-Abubakar Malam

Ademọla Adepọju

203

Mínísítà fún ètò ìdájọ́ lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà,Abubakar Malami, ní ìwádìí ti fihàn pé  àwọn ènìyàn ńlá àti olówó kan ló ń fowó sèrànwọ́ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ lórílẹ̀ èdè Naijiria, àwọn ko si ni pẹ́, pè wọ́n lẹjọ́.

Malami sọrọ yii lọjọ Ẹti, niluu Abuja lasiko to n ba awọn akọroyin ile aarẹ sọrọ , lẹyin  adura ti wọn ṣe ni mọsalasi ile aarẹ.

o ni : “Ni awọn ọdun kan sẹyin, awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria kan lọwọ lati maa se agbodegba fun awọn ọlọtẹ nipa sise iranwọ owo fun wọn lati orilẹ ede  United Arabs Emirate , ni eyi  ti yoo ran orilẹ ede Naijiria lọwọ ninu iwadii yiii.

“Iwadii si n lọwọ , o digba ti iwadii  ba pari , ki a to mọ iye awọn ti wọn lọwọ nibi isẹ ibi ọhun,, sugbọn mo fi n daa yin loju pe iye wọn ko mọ niwọnba.”

O tun fi da gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria loju pe  ko si ninu gbogbo awọn onisẹ ibi wọnyi, ti ijọba yoo daa silẹ” 

Leave A Reply

Your email address will not be published.