Àwọn àjọ tó wà nípa ètò ìdìbò ni orílẹ̀-èdè Pakistan ti kéde pé ètò ìdìbò àpapọ̀ pálíámẹ̀ntì tí wọ́n ti ń retí yóò wáyé ni ọsẹ̀ tó kẹ́yìn oṣù kínní,ọdún tó ń bọ̀.
Nínú àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àjọ Election Commission of Pakistan, ECP sọ pé ó pan dandan láti se èyí fún àtúnṣe gbogbo àgbègbè àti ẹ̀ka káàkiri orílẹ̀-èdè lẹ́yìn ètò ìkànìyàn tó kọjá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ìbò dídì pàtó náà ni won kò tíì sọ.
Ìròyìn ròó pé ìbò ni Pakistan yẹ kó wáyé láàrin àádọ̀rún ọjọ́ bi òfin wọn se la kalẹ̀ lẹ́yìn tí pálíámẹ̀ntì tó ń kógbá wọlé ti lo ọdún màrún rẹ̀ pé ni ọjọ́ kẹsàn án oṣù kẹjọ, Olórí orílẹ̀-èdè, Shehbaz Sharif sí ti tú ilé ká.
Olórí orílẹ̀-èdè Pakistani jẹ́ olósèlú tó gbajúmọ̀ julọ nilẹ̀ náà , ẹgbẹ́ oselu rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ́ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ ní orílẹ̀-èdè náà bí àwọn ènìyàn se sọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply