Take a fresh look at your lifestyle.

Ó seése Kí Osimhen Gba Àmì Ẹ̀yẹ Ballon d’Or

0 333

Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ikọ̀ Super Eagles, Jose Peseiro, ti sọ pé  òun gbàgbọ́ pé, Victor Osimhen leè gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d’Or
ni ọjọ́ iwájú.

Osimhen wà lára agbábọ́ọ̀lù Ọgbọ̀n ti wọ́n yàn láti díje fún àmì ẹ̀yẹ ti ọdún 2023 náà.

Ọ̀dọ́mọdékùnrin ọmọ ọdún Mẹ́rìndínlógún náà ni gbogbo àmúyẹ ti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń dìje ní láti se àseyege, ó tún ń gbá bọ́ọ̀lù sí àwọ̀n dáradára “.

Agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ iwájú náà tún wà lára àwọn tí wọ́n yàn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù Ọkùnrin tó yanrantí jùlọ ti Àmì ẹ̀yẹ àjọ FIFA.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button