Take a fresh look at your lifestyle.

Niger Coup: Aṣojú ECOWAS Ṣé Ìpàdé Pẹ̀lú Ààrẹ Mohamed Bazoum Tí Àwọn Ológun Yọ́

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 256

Aṣojú ECOWAS àtí Alákóso Iṣé ìjọba túntún ní Chad, Mahamat Déby Itno tí pàdé pẹ̀lú Ààrẹ Niger Republic, Mohamed Bazoum, ní Olú-ìlú Niger, Niamey.

O jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí Ààrẹ náà ní anfààní látí gbàléjò lẹyìn ìgbà tí àwọn ológun yí tí gbá ìjọba ní ọsẹ tó kọjá.

Ọ̀gbẹ́ni Déby ń gbìyànjú láti parí àáwọ̀ tó ń ṣẹ̀lẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè náà lẹyìn tí àwọn àdári Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà ECOWAS tí fún àwọn afi ipá gbajọba náà ní ọjọ́ meje látí fí ipò náà sílẹ̀ tàbí kojú ogún.

O tún ṣé ìpàdé pẹ̀lú olórí ìjọba túntún náà, èyí tí Gen. Abdourahmane Tchiani, kéde àrà rẹ̀ bí olórí títún Niger ní ọjọ́ Ẹtì.

Ọ̀gbẹ́ni Déby sọ pé ìgbìyànjú ìlàjà rẹ̀ ní ìfọkànsí látí wá “ojútùú àlàáfíà sí aawọ tó wà nílẹ̀” Niger, ẹlẹgbẹ rẹ̀ ní Chad.

Kó ṣé àlàyé síwájú síi, ṣùgbọ́n ọfiisi rẹ̀ gbé fọto kàn jáde níbí tó tí joko l’ẹba Ọ̀gbẹ́ni Bazoum tó ń rẹrin musẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button