Mínísítà Ìròyìn Uganda, Chris Baryomunsi, tí b’ẹnú àtẹ lù ìkọlù àwọn ológun sí ilé alátakò ìjọba Bobi Wine ní oṣù tó kọjá.
Ó sọ pé olóṣèlú olórin tẹ́lẹ̀ náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, ó sì ní òmìnira láti padà síbẹ̀.
Wine ti sá sí ìpamọ́ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tó sá kúrò nílé rẹ̀ ní olú-ìlú Kampala, ní wákàtí díẹ̀ kí wọ́n tó kéde pé òun ló gba ipò kejì sí Ààrẹ Yoweri Museveni nínú ìdìbò Ààrẹ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kìíní.
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kìíní, Wine sọ pé òún ti gbé ìyàwó òun lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí àwọn ológun ti wọ ilé wọn, Ó sọ pé wọ́n bọ́ aṣọ wọn, wọ́n sì fún un ìyàwó òun ní ọrùn mọlẹ.
Olórí ológun Uganda, Muhoozi Kainerugaba, tó tún jẹ́ ọmọ Museveni, sọ pé àwọn ológun kò fiya jẹ́ ìyàwó Wine, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ó sọ ní orí opo X pé àwọn ti “mú un Ìyàwó Wine, lẹ́yìn náà wọ́n sì ti tú u sílẹ̀.”
Baryomunsi, ẹni tó tún jẹ́ agbẹnusọ fún ìjọba, sọ pé àwọn aláṣẹ yóò ṣe ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Comments are closed.