Ẹgbẹ́ Àwọn Onímọ̀ Ẹ̀rọ Nàìjíríà, NSE sọ pé ìgbéjáde èsì ìdìbò pẹ̀lú ẹ̀rọ alátagbà ní àkókò ní i ṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ìmọ̀ ẹ̀rọ tó lè mú kí ìdúróṣinṣin, ìṣiṣẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ìlànà ìdìbò Nàìjíríà pọ̀ sí i.
Ààrẹ NSE Ali Alimasuya Rabiu sọ èyí nínú ìròyìn kan.