Minisita Russia fun Oro ilẹ̀ Ajeji, Sergey Lavrov ba akẹgbẹ Egipiti, Badr Abdelatty sọrọ ní Moscow ni ọjọ Ẹti.
Ipade wọn dojukọ lori mimu awọn ibatan meji laarin Russia ati Egypt lagbara, ati atunyẹwo awọn ọran pataki lori ọrọ agbaye. Awọn minisita mejeeji tun ṣe sọrọ lori ipo ti apa àárín gbùngbùn, Middle East wa.
Russia ati Egypt ṣe atilẹyin fun “idaduro ogun ni kiakia ati ipadabọ si ilana iṣelu ati ti ijọba,” ni agbegbe naa, Lavrov sọ lẹhin awọn ijiroro naa.
Minisita Russia tun ṣe akiyesi pe ipinnu ti Bahrain fi silẹ nipa Strait of Hormuz, ti Igbimọ Aabo ti àjọ Agbaye, United Nations Security Council, n jiroro lọwọlọwọ, le ba awọn ijiroro jẹ tabi “jẹ ki a lo lati fi ofin mu ibinu lodi si orílẹ-èdè Iran pada.”
Abdelatty tẹnumọ pataki awọn idunadura, o sọ pe “gbogbo eniyan n padanu, agbaye n padanu ati pe agbegbe naa n padanu.”
Temitọ́pè Òbísẹ̀san