Ìkọ tó gbá ìfé English Premier League ní sáà tó kọjá Manchester City tí parí ìforúkọsílẹ tí àgbábọ́ọ̀lù lọ́wọ́ ẹyìn Ọmọ Orílẹ̀-èdè Croatian Josko Gvardiol látí inú ìkọ RB Leipzig tí German lórí àdéhùn ọdún márún.
Gvardiol, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún 21, darapọ̀ mọ́ Leipzig látí Dinamo Zagreb ní ọdún méjì sẹyìn o sí ṣoju ìkọ náà dáradára nínú ìdíje Bundesliga, tó sí gbá ìfé German Cup ní àwọn àkókò méjèèjì.
Gvardiol ní bayi dì àgbábọ́ọ̀lù Kejì tó tọ́wọ́bọ́ ìwé àdéhùn pẹ̀lú ìkọ Manchester City lẹyìn àkẹgbẹ́ rẹ̀ Mateo Kovacic.
Àgbábọ́ọ̀lù náà tí ṣojú Orílẹ̀-èdè Croatia ní ìgbàmọ́kànlélógún 21 àtí pé o jẹ́ ọkàn nínú àwọn àgbábọ́ọ̀lù Croatia tó dé ìpele aṣé kágbá níbí ìfé ẹ̀yẹ àgbáyé FIFA World Cup 2022.
Leave a Reply