Ikolọ̀ Super Eagles ti Nàìjíríà yóò kojú Poland àti Portugal nibi ayo olooresore ní oṣù kẹfà gẹ́gẹ́ bí ara ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ìdíje gbogbo to ń bọ̀, gẹ́gẹ́ bí àjọ NFF ti sọ.
Ìkọ olubori agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ó ti gba ade ẹ̀yẹ náà nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà ń fẹ́ láti kọ́ láti tẹpá mọ́sẹ́ bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀ fún àwọn ìdíje tí oń bọ̀.
Ìfagagbága pẹ̀lú ikọ Poland yóò wáyé ní pápá isere PGE Narodowy ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Warsaw ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà, nígbà tí ìjà pẹ̀lú Portugal yóò wáyé ní Portugal ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹfà, pẹ̀lú ibi tí wọ́n yóò ti gbaa ti wọn yóò kéde rẹ̀ ní ọjọ́ to ń bọ̀.
Ìfagagbága pẹ̀lú Portugal yóò jẹ́ eré ìkẹyìn fún àwọn olùgbàlejò kí wọ́n tó fò lọ sí ìwọ̀ oòrùn jíjìnnà láti kópa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí, tí USA, Canada àti Mexico yóò gbàlejò papọ̀.
Àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tún ti ṣètò láti dáàbò bo adé wọn nínu ìdíje Unity Cup ti ọdún yìí ní London, tí yóò wáyé láti ọjọ́ kẹrìndínlógbọ̀n sí ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù karùn-ún.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san