Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance (APGA) ti gbà ìgbékalẹ̀ Òfin Ìdìbò tuntun orílẹ̀-èdè yii, wọ́n yin Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún fífọwọ́ sí òfin náà ni kíákíá, wọ́n sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ sí fífún àwọn ìlànà ìjọba tiwantiwa lágbára kí ó tó di ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2027.
Ẹgbẹ Òṣelu APGA tún yin Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè yìí fún ìgbékalẹ̀ òfin náà kíákíá, wọ́n tẹnu mọ́ àwọn ètò bíi àtúnṣe sí àwọn ìpele ìpele oṣèlú àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú níti ẹ̀rọ ayélujára.
Ẹgbẹ́ náà sọ pé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí bá àwọn ìlànà tó dára jùlọ kárí ayé mu, wọn yóò sì fún ìjọba tiwantiwa ẹgbẹ́ òṣèlú lágbára, nígbà tí wọ́n ń rọ ajọ INEC láti ṣe àtúnṣe ìpele akoko ìdìbò ọdún 2027 rẹ̀ pẹ̀lú ìlànà òfin tuntun.
Àjọ amuṣẹ́se NWC sọ pé wọ́n ti ṣe àtúnyẹ̀wò ìṣètò inú rẹ̀ fún ìdìbò, títí kan fífọwọ́ sí àwọn ìlànà àti ìpele akoko ìdìbò àkọ́kọ́ ọdún 2026 wọn.
Ó tún kéde ètò láti pe àwọn ìpàdé àwọn alenulọ́rọ̀ káàkiri àwọn agbègbè mẹ́fà ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú ìsapá ìgbékalẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú.
Nípa ìṣàkóso ẹgbẹ́ òṣèlú, APGA gbà pé àwọn ìpèníjà wà nínú ìforúkọsílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àtúnṣe ìfọwọ́sípò ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lójú pé wọ́n yóò yanjú àwọn ọ̀ràn náà kíákíá.
Ó gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun àti àwọn tó wà nípò láti kópa nínú ìlànà náà.
Ìgbìmọ̀ náà tún fọwọ́ sí pípa àwọn ètò ẹgbẹ́ òṣèlú run ní Agbègbè Olú-ìlú ìjọba Àpapọ̀, ó mẹ́nu ba “àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń yọni lẹ́nu”, ó sì sọ pé wọ́n yóò gbé ìgbìmọ̀ olùtọ́jú kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin ẹgbẹ́ òṣèlú lẹ́yìn tí wọ́n ti fi tó INEC létí.
Ẹgbẹ Òṣelu APGA lo ìpàdé náà láti kí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra Chukwuma Soludo kú oríire fún ìgbéga sí ipò Gómìnà rẹ̀ ní ìgbà kejì, ó sì sọ pé ìyípadà rẹ̀ jẹ́ nítorí ohun tí wọ́n pè ní ìlọsíwájú ìdàgbàsókè pàtàkì ní ìpínlẹ̀ náà.
Ẹgbẹ́ náà rọ̀ ọ́ láti tẹ̀síwájú nínú ìsapá láti yí Anambra padà sí “ìlú ńlá tí ó dára tí ó sì ní ìlọsíwájú.”
Nínú ìdàgbàsókè oṣèlú mìíràn, APGA yin Ààrẹ ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin, Godswill Akpabio àti àwọn aṣòfin mìíràn fún ohun tí wọ́n pè ní dídààbòbò ìlànà òfin, lẹ́yìn tí Sẹ́nétọ̀ Enyinnaya Abaribe kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Wọ́n ké sí Sẹ́nétọ̀ láti kéde pé ipò náà ṣófo ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òfin.
Ẹgbẹ́ náà tún rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti àwọn aláṣẹ rẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà láti máa tẹ̀lé àwọn òfin ẹgbẹ́ òṣèlú náà dáadáa, wọ́n kìlọ̀ pé ìrúfin nígbà ìdìbò àkọ́kọ́ tó ń bọ̀ yóò fa ìjìyà.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san