Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ṣàlàyé ìpàdé Tinubu pẹ̀lú àwọn afaragbà ní pápákọ̀ òfurufú
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ti ṣàlàyé ìdí tí Ààrẹ Bọla Tinubu fi bá àwọn afaragbà ìkọlù tó ṣelẹ̀ láìpẹ́ yìí ṣèpàdé ní Plateau, ní pápákọ̀ òfurufú Yakubu Gowon dípò ṣíṣe àbẹ̀wò sí àwọn agbègbè tí ìkọlù náà ti wáyé, ó sọ pé àwọn ìdíwọ́ tí ó le ṣẹlẹ̀ látàrí ìpèsè gbígbé lọ, gbígbé bọ̀ tí yóò ṣe ní ṣíṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ náà ni ó fàá.
Alaye kan ti oludamọran Aarẹ pataki lori ibaraẹnisọrọ ọlọgbọn, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga fi sita ni ọjọ Ẹti, o wi bayi pe irin ajo Aarẹ si ilu Jos waye ni pajawiri ti o si ni lati ṣe awon atunṣe ninu bi o ṣe ṣeto irin rẹ silẹ tẹlẹ, lẹyin igba ti Gomina Caleb Mutfwang ṣalaye bi ikọlu naa ṣe burujai si.
Ọgbẹni Ọnanuga wa ṣalaye pe Aarẹ Tinubu fẹ gbalejo Aarẹ orilẹ-ede Chad, Mmuhamat Idriss Deby Itno ni Abuja tẹlẹ, ki o si kọja si Ipẹru, ni Ipinlẹ Ogun lẹyin naa, ṣugbọn o ni lati lilọ si Ogun duro, ki o kọkọ ṣe abẹwo si Plateau.
Alaye naa tẹ siwaju pe nigba ti o de Jos, idiwọ asiko ati ofurufu ko jẹ ko rọrun fun un lati lọ si arin ilu lati papakọ ofurufu, lati ṣe ipade pẹlu awọn afaragba Angwan Rukuba, ki o si pada si papakọ ofurufu ki ilẹ to su, nitori pe oju ọna ko dara fun irin ajo alẹ latari aisi irọrun itọsọna.
Oluranlọwọ Aarẹ tun wa sọ pe awọn aṣakoso ipinlẹ ati orilẹ-ede lapapọ ba kuku ko awọn aṣoju agbegbe ti ọrọ naa kan sinu gbọngan kan to wa lẹgbẹẹ papakọ ofurufu naa ki Aarẹ o le fi ṣepade pẹlu wọn ni kiakia, petu siwọn ninu, ki o si tẹti gbọ ẹdun ọkan wọn lai ru ofin ihamọ aabo irinajo lori ofurufu.